ILẸ HGUALA

Planet Mars
Ilẹ Hguala
Ilẹ Iguala
Ulẹ Uguala

Hguala jẹ́ ọkàn lára àwọn ilẹ̀ méje tó nyí orun ká .
Fún igba pipẹ là tí nwo ilẹ̀ na lókèèrè rere. igbagbọ wa ni pe, ó ṣeṣe kò jẹ ilẹ alaye. Igbagbọ yi, lo mu wa l ọkàn, láti igbadegba, ta fi n gbójú sókè, woo ilẹ̀ na, pelu àwọn iwogbe  afaajinmọra.
Nínú àwọn ìwogbé tá tí lo, ọkàn pàtàkì ni iwogbe Ọọbu. Ṣe ni iwogbe na fà ilẹ̀ pupa hguala sún mọ́ wa pẹ́kípẹ́kí. O fún wa ní imọlára tí a lè fi ṣe àkàwé pé, a wá lórí ilẹ̀ na gan. 
Lai ṣàlàyé jìnnà, àwọn ohun tá f ojú rí nípasẹ̀ iwogbe Ọọbu, wá nínú ohun tó tá wá jí, làti bẹ̀rẹ̀ itọpinpin ilẹ̀ hguala. Àmọ́, bí itaniji wá ṣe lágbára tó, bẹ ní ìṣòro tí ó rọ mọ. Ìṣòro na ni ti ìdiwọ̀n ibusọ tó wà larin ilẹ̀ wá sì ilẹ̀ na. Ìdiwọ̀n ibusọ na là ṣí si, ọ̀kẹ́ mẹta di ladoje (147,000000). 
Láti ìhìn sí ọun, bí ọkọ iroke wa, alárè iná, bá gbéra, lai dúró rara, yio gbaa ni oṣù mẹ́fà, kí ó tó lè gunlẹ sì hguala. Nípa ìwòye, irìnàjò na yio kọjá eyiti ènìyàn lè farada, nítorí òru àti ìnira inú ọkọ tí ó lè ṣe kú pa ni. 
Níhìn láti dá ro pe, ao ni lè lọ sí ilẹ hguala lásìkò yí, ṣùgbọ́n, a lè ràn àwọn iribi lọ. 

Comments

Popular posts from this blog

THE MEANING OF FUJI

AJA = DOG